TITILOPE(yoruba version)






Eyebiokin ko pe meji lawujo,
Yoruba ni won ni ijimere baba obo,
Tori ewa ni okin se je oba eye,
Be sire tori agbara ni ijimere se je oba obo.

Titilope, obinrin to dangajia,
To fun ni ni ireti nibiti o ti pin,
To bomirin okan eni bi ojo olodumare,
Gbogbo okunrin lo fe fi iru Titilope saya....


Adumaradan mi owon,
Orebe ti re ibi aye danu,
Iwa tutu bi adaba ni eso re,
Eleyin funfun bi egbon owu,
Biba n koja lo ikebe re a si ma seju simi
Ara mi a si wa le siiiii


Gbogbo okunrin se aferi re bi ola olodumare,
Biba n lo won a si ma pe loruko to rewa,
Bi akoba niru eyi laya a si fi se ale,
Afi ki eledua di eti si adura won,
Titilope! odaju obinrin to so okunrin sinu hilahilo pelu ewa re....


Ajanaku ewa re koja mori nkan firi,
Ta ba ri omobinrin to rewa to niwa eja kaso,
Titilope, okan soso ajanaku ewa,
To mi igbo obinrin kijikiji........



Titilope, mo wo titi mo sope lodo eledumare,
Ife okan mi ti fi erin pa ironu re,
Ti fi enu komilenu nigba iponju,
Titilope! obinrin ti wuni lati fi se aya nigba ifoya...........


HighJustice®